Gomina AbdulRazaq yan ọmọ ọdun mẹrindinlọgbọn, Muka Ray, Ọjọgbọn Jimba ati awọn miran s'ipo oṣelu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, October 20, 2023

Gomina AbdulRazaq yan ọmọ ọdun mẹrindinlọgbọn, Muka Ray, Ọjọgbọn Jimba ati awọn miran s'ipo oṣelu


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti bu ọwọ lu iyansipo ọmọ ọdun mẹrindinlọgbọn kan, Salami Wasiu Onidugbẹ s'ipo amugbalẹgbẹ pataki lori ọrọ to nii ṣe pẹlu awọn akẹkọọ (Special Assistant on Student Affairs).

Yatọ si eyi, Gomina AbdulRazaq tun buwọ lu ipadabọsipo gbajugbaja oṣere tiata nni, Ọnarebu Eyiwumi Muka Aramide, ẹni ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Muka Ray gẹgẹ bi amugbalẹgbẹ agba pataki lori ọrọ to nii ṣe pẹlu Aṣa ati Irin Ajo Afẹ (Senior Special Assistant on Culture and Tourism)

Bakan naa ni gomina tun kede Imam Mariam Nnafatima gẹgẹ bi amugbalẹgbẹ agba pataki lori ọrọ to nii ṣe pẹlu idagbasoke afojusun (Senior Special Assistant on Sustainable Development Goals, SDGs)

Awọn miran ti gomina tun yan ni Hajia Aishat Yusuf gẹgẹ bi amugbalẹgbẹ agba pataki lori ọrọ to nii ṣe pẹlu awọn darandaran (Herdsmen Community Outreach); Ọjọgbọn Mashood Mahmood Jimba gẹgẹ bii alaga igbimọ fun ileeṣẹ to n ri sọrọ irin ajo lọ si ile mimọ awọn Musulumi n'ipinlẹ naa (Kwara State Muslim Pilgrims Board).

Ẹnikan yooku ni Ọjọgbọn Timothy Opoọla gẹgẹ bii alaga igbimọ to n ri sọrọ irin ajo lọ si ile mimọ awọn Kristẹni n'ipinlẹ naa (Kwara State Christian Pilgrims’ Welfare Board).

Ninu atẹjade ti akọwe ijọba Kwara, Rafiu Ajakaye gbe jade lo ti sọ pe yiyan ti gomina yan awọn eeyan wọnyii lo nii ṣe pẹlu ipa ti wọn ti ko ni ẹka ibi ti wọn yan onikaluku wọn si, to si ni iṣẹ wọn bẹrẹ loju ẹsẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI