Inu mi dun fun iyansipo Amofin Gafar - AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, October 31, 2023

Inu mi dun fun iyansipo Amofin Gafar - AbdulRazaq


Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti sọ pe idunnu nla lo jẹ foun lati gbọ nipa bi Aarẹ Bọla Tinubu ṣe yan Amofin Jumọkẹ Monsurat Gafar.

AbdulRazaq ni oun fọwọ sọya wi pe Gafar yoo ṣe daadaa ni ipo amugbalẹgbẹ pataki lori ọrọ to nii ṣe pẹlu ijọba awọn ileeṣẹ, eyi ti a mọ si Coordination and Intergovernmental Agency Relations.

Aarẹ Bọla Tinubu lo kede Amofin Gafar laipẹ yii, to si ni iṣẹ rẹ bẹrẹ ni waranṣeṣa.

Amofin Gafar ti ṣiṣẹ tẹlẹ gẹgẹ bi Principal Private Secretary ko to di pe Aarẹ Tinubu yan an.

AbdulRazaq wa dupẹ lọwọ Aarẹ fun anfaani to fun Amofin Gafar lati sin orileede Naijiria.

Bẹẹ lo dupẹ lọwọ Amofin Gafar lori awọn ipa to ti ko lasiko to fi wa gẹgẹ bi Principal Private Secretary.

O loun ni igbagbọ pe yoo fi ọkan akikanju ati ifarajin ṣiṣẹ ti wọn gbe le lọwọ daadaa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI