Ẹgbẹ awọn obinrin Naijiria fi awọọdu nla da AbdulRazaq, gomina ipinlẹ Kwara lọla (Fọto) - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, October 29, 2023

Ẹgbẹ awọn obinrin Naijiria fi awọọdu nla da AbdulRazaq, gomina ipinlẹ Kwara lọla (Fọto)


Agbarijọ awọn obinrin lorileede Naijiria ti gbe aami ẹyẹ idalọla fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara lori bo ṣe n yan awọn obinrin si ipo oṣelu.
 
Ilu Abuja ni eto ayẹyẹ idalọla naa ti waye, ti wọn si ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi akikanju aṣiwaju to n fi ti awọn obinrin ṣe.

 
Wọn ni bo ṣe n fi awọn obinrin si awọn ipo oṣelu to ṣe pataki nipinlẹ Kwara, to si tun n ṣatilẹyin fun wọn ninu idagbasoke ati ilọsiwaju Naijiria, o pọn dandan lati bu ọla ati iyi fun un.

Lara awọn apẹẹrẹ ti wọn mẹnuba ni minisita fọrọ iidagbasoke ohun to nii ṣe pẹlu awọn ọdọ, Ọmọwe Jamila Bio Ibrahim, ẹni to ti figba kan ri jẹ oludamọran pataki lori eto idagbasoke, SDGs.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI