Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti sọ pe gbogbo eto lo ti fẹẹ pari fun gbọngan ati gbagede ti awọn to yan iṣẹ tiata laayo lati figagbaga pẹlu awọn oyinbo alawọ funfun, idi pataki to fi l'awọn n kọ gbagede naa to pe ni Kwara Sugar Film Factory.
AbdulRazaq sọ pe gbagede ti wọn ṣẹṣẹ kọ yii, yoo pese ọpọ iṣẹ fun awọn ọdọ, bakan naa ni yoo tun mu ki iṣẹ sinima rọrun f'awọn onitata lọna igbalode.
Siwaju sii lo sọ pe ojoojumọ ni idagbasoke n ba awọn oṣere tiata nipa kikọ fiimu igbalode loorekoore, idi ree to fi ni o ṣe pataki pupọ lati dide iranwọ fun wọn.
Gomina AbdulRazaq nigba to n ṣabẹwo si gbagede naa l'Ọjọru tii ṣe Wẹside, ọsẹ yii jẹ ko di mimọ pe lara awọn akanṣe iṣẹ pataki toun yo maa fi ọwọ rẹ sọya ni gbogbo igba ni Kwara Sugar Film Factory yii.
O ni yoo gbajumọ idagbasoke eto ọrọ aje ipinlẹ naa, paapaa nipa igbani-si-iṣẹ, irolagbara awọn ọdọ, ati igbe aye irọrun igbalode to jọju.
Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe awọn fẹ ki ipinlẹ Kwara maa lewaju nipa iṣẹ sinima ati lilo imọ ẹni nilẹ adulawọ, ati pe lara orukọ igbaani Tate and Lyle Sugar Factory to parun l'ọdun 90s l'awọn ti mu orukọ naa.
No comments:
Post a Comment