Gbajuẹ mẹta ha sọwọ ọlọpaa RRS n'Idumọta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, October 11, 2023

Gbajuẹ mẹta ha sọwọ ọlọpaa RRS n'Idumọta


Ileeṣẹ ọlọpaa Rapis Response Squad ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ awọn mẹta kan ti wọn ko ni iṣẹ meji ju gbajuẹ lọ niluu Ekoo, ati pe agbegbe Idumọta lọwọ palaba wọn ti segi.

Wọn ni ibi ti wọn ti n gbiyanju lati lu ọdọmọbinrin, ẹni ọdun mẹtalelogun kan ti wọn fi orukọ bo laṣiri ni jibiti lọwọ palaba wọn ti segi.
 
Ọmọbinrin naa ni iroyin fi to wa leti pe o wọ mọto Volkswagen Vento wọn to ni nọmba idanimọ BDG 513 EJ wọn lagbegbe Iyana Oworo, to si n lọ si Ikoyi lai mọ pe gbajuẹ ni wọn.
 
Mọto ti wọon fi n ṣiṣẹ
 
A gbọ pe kaka ki wọn gbe ọmọbinrin naa lọ si ibi to n lọ, niṣe ni wọn fi tipatipa gbe e lọ si Idumọta, nibi ti wọn ti le raaye ṣiṣẹ buruku wọn.
 
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa RRS naa gbe jade, wọn darukọ awọn mẹtẹẹta naa bii Austin Okoro, ẹni ọdun mẹtadinlaadọta to jẹ olori wọn; Godwin Asezour, ẹni ọdun mẹrinlelaadọta ati Susan Elohor, toun jẹ obinrin, ẹni ọdun mejilelogoji ti wọn jọ n ṣiṣẹ.
 
Wọn ni niṣe ni wọn n gbiyanju lati fa a wọnu jibiti owo ti wọn fi n tan awọn eeyan jẹ, ṣugbọn tiyẹn sọ pe oun ko ṣe.
 
Nibi ti wọn ti n lọ ni wọn sọ pe ọmọbinrin naa ti kofiri awọn ọlọpaa RRS, to si pariwo sita fun iranlọwọ, eyi to jẹ ki wọn sare le wọn mu.
 
RRS naa jẹ ko di mimọ pe awọn ti foju awọn mẹtẹẹta ba ile-ẹjọ lẹyin ti iwadii ti pari lati ọdọ ọga wọn, CSP Olayinka Egbeyemi-led RRS.

Mọto ti wọon fi n ṣiṣẹ

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI