Orí kó Gómìná Yahaya Bello yọ lọ́wọ́ ikú òjijì - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, October 22, 2023

Orí kó Gómìná Yahaya Bello yọ lọ́wọ́ ikú òjijì


Kani kii ṣe ori to ko gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello yọ lọwọ iku ojiji, boya ọtọ ni iroyin ti a ko ba maa kọ bayii, pẹlu bi wọn ṣe sọ pe awọn agbanipa lọ dena de loju ọna, ti wọn si fẹẹ pa a danu.

Irọlẹ oni, ọjọ Aiku, Sannde la gbọ pe awọn agbanipa naa kọlu Gomina Bello ati ikọ akọwọrin rẹ lasiko to n lọ siluu Abuja.

Gẹgẹ bi kọmiṣanna fọrọ eto iroyin nipinlẹ Kogi, Kingsley Fanwo ṣe sọ, o ni ibi ẹtọ kan to ṣe pataki ni Gomina n lọ, ko to di pe awọn agbanipa naa ti wọn wọ aṣọ ologun daa lọna, ti wọn si ṣina ibọn bolẹ fun un.

Fanwo sọ pe kilomita diẹ lo ku ki wọn de ilu Abuja, ni wọn pade awọn agbanipa naa ti wọn wọ aṣọ ologun, ṣugbọn ti wọn kii ṣe ologun rara. O sọ pe nnkan bi aago mẹrin irọlẹ oni, ni iṣẹlẹ naa waye.

O ni bi wọn ṣe da gomina ati ikọ akọwọrin rẹ lọna ni wọn ti da ibọn bo mọto rẹ ati awọn mọto to tẹle e, to si ni awọn ẹṣọ aabo ti wọn tẹlẹ gomina lo koju wọn loju ẹsẹ, ko to di pe wọn salọ.

Fanwo bu ẹnu atẹ lu awọn alatako oṣelu, bi eto idibo idibo ipinlẹ naa ṣe n sunmọ etile.

Ọjọ kọkanla, oṣu kọkanla, ọdun 2023 ni eto idibo gomina yoo waye n’ipinlẹ Kogi, ti awọn oludije si ti bẹrẹ ipolongo lọtun losi kaakiri ipinlẹ naa.

Fanwo sọ pe deedee aago mẹrin kọja ogun iṣẹju ni awọn agbanipa naa da wọn lọna lagbegbe mẹta ọtọọtọ to wa ni Kwali Federal Capital Territory, to si l’awọn ti fi to gbogbo awọn ileeṣẹ eleto aabo leti lati bẹrẹ iṣẹ iwadii wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI