AbdulRazaq lewaju awọn gomina Naijiria lọ sọdọ ajọ BMGF fun ilọsiwaju (Fọto) - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, November 25, 2023

AbdulRazaq lewaju awọn gomina Naijiria lọ sọdọ ajọ BMGF fun ilọsiwaju (Fọto)


Lati le mu ilọsiwaju ati idagbasoke ba eto anfaani agbaye, olori awọn gomina Naijiria to tun jẹ gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq lo ti lewaju gbogbo awọn gomina lọ si ileeṣẹ ajọ kan ti wọn pe ni Bill and Melinda Gates Foundation (BMGF).

Ajọ na ti gbajugbaja Rodger Voorhies, alakoso Global Growth and Opportunities to ni BMGF ni awọn alakoso ipinlẹ ni Naijiria lọ ṣe abẹwo si fun ifọwọsowọpọ.

Sẹkitariati awọn gomina ni Naijiria ni ipade idagbasoke ọhun ti waye, nibi ti gbogbo gomina mẹrindinlogoji to wa ni Naijiria ti peju pesẹ.

Nibi ipade naa ni wọn ti jiroro nipa iranwọ ti yoo waye lori ọna lati mu idagbasoke ba iṣẹ agbẹ ati ọgbin, pipa iṣẹ ati o0ṣi run, eto ilera, to fi mọ igbayegbadun araalu.

Aarẹ ajọ naa, Ọgbẹni Rodger Voorhies rọ ijọba apapọ Naijiria lati ṣiṣẹ lori idagbasoke ilu lọna igbalode (digital infrastructure).

O ni bo tilẹ jẹ pe Naijiria ti gbiyanju lori eyi, ṣugbọn wọn tubọ nilo lati ṣiṣẹ takuntakun sii.

Fọto:






No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI