Ẹ wa gbọ nnkan ti AbdulRazaq sọ nipa minisita f'ọrọ eto idajọ ni Naijiria - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, November 25, 2023

Ẹ wa gbọ nnkan ti AbdulRazaq sọ nipa minisita f'ọrọ eto idajọ ni Naijiria


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti ṣapejuwe Minista f'ọrọ eto idajọ lorileede Naijiria, Ọmọọba Lateef Fagbemi gẹgẹ bi aṣiwaju tootọ, ati ẹni to ṣee fọkan tan.

Ọjọ Ẹti, Fraide, ọsẹ yii ni AbdulRazaq sọrọ naa niluu Ilọrin nibi akanṣe adura ti awọn agba aafa ṣe fun Amofin Fagbemi.

Lara awọn to kọwọrin pẹlu gomina ni igbakeji aarẹ ile igbimọ aṣofin agba, Sẹnetọ Lọla to n ṣoju ẹkun Kwara South; Sadiq Umar (North); Turaki ilu Ilọrin, Sẹnetọ Saliu Mustapha (Central); Ọnarebu Raheem Tunji Ajulo-opin; Ọnarebu Rasaq Owolabi; ati Kọmiṣanna f'ọrọ awọn obinrin Ọnarebu Bọsẹde Ọlaitan Buraimoh; awọn oloye ẹgbẹ APC ati awọn miran.


Awọn ọba alaye bii Ọlọfa tiluu Ọffa, Ọba Muftau Gbadamọsi Eṣuwoye II; Olupo tiluu Ajaṣẹ-Ipo, Ọba Ismail Yahaya Alebioṣu; the Onijagbo tiluu Ijagbo, Ọba Ṣarafadeen Buhari Adeniyi; Olojoku tiluu Ojoku, Abdulrasaq Afolabi; Onira tiluu Ira, AbdulWahab Oyetoro; ati Olukotun tiluu Ikotun AbdulRazaq Adebayo Abioye ni wọn wa nibẹ.

Idile agba amofin naa, Fagbemi lo gbe akanṣe adura ọhun kalẹ, ti iyawo at'awọn ọmọ rẹ naa si wa nibẹ.

Imaamu agba ilu Ọffa ati Sheik Ijagbo, Muyideen Salman Hussain ati Sheikh Muftau. 

Nibẹ ni gomina ti ṣapejuwe Ọmọọba Fagbemi gẹgẹ bi alaṣeyọri amofin to tun jẹ ogo ipinlẹ Kwara to ti fi ipo re ṣiṣẹ sin ilu ati orileede Naijiria lapapọ.

O gbe oriyin fun minisita naa fun iwa ọmọluwabi ati iwa rere to n fi apẹẹrẹ rẹ lelẹ fun awọn to n bọ lẹyin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI