AbdulRazaq tun ra awọn irinṣẹ iwosan igbalode si ọsibitu Omu-Aran ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, November 16, 2023

AbdulRazaq tun ra awọn irinṣẹ iwosan igbalode si ọsibitu Omu-Aran ni Kwara


Lati le jẹ ki eto ilera to peye kari fun anfaani araalu, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara tun ti fi awọn irinṣẹ ayẹwo ati itọju igbalode si ọsibitu ijọba to wa niluu Omu-Aran.

Awọn alakoso to n ri sọrọ awọn ọsibitu ni Kwara, Kwara State Hospital Management Board ni wọn lọ ko awọn irinṣẹ igbalode naa fun awọn alakoso ọsibitu ijọba ti Omu-Aran.

Nigba to n gba ẹnu gomina sọrọ, Dokita agba ni ọsibitu ọhun, Dọkita Oguntoye sọ pe lara awọn irinṣẹ naa ni Hematology Analyzer, Chemistry Analyzer, Electrolyte analyzer ati awọn nnkan miran.
 
O ni awọn irinṣẹ naa yoo mu adinku ba ri rin irin ajo lọ ba itọju, ti yoo si mu kawọn araalu bẹrẹ sii jẹ anfaani eto ilera igbalode.

Siwaju sii lo sọ pe iwuri nla ni yoo jẹ fun awọn ara ati olugbe ilu Omu-Aran ati agbegbe rẹ, nitori pe wọn ko nii lọ silu Ilọrin mọ, ko to di pe wọn gba itọju to peye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI