Awọn to n ṣakoso Naijiria ko ṣe ohun to yẹ lati mu orileede yii tẹsiwaju - Ọjọgbọn Salami - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 6, 2023

Awọn to n ṣakoso Naijiria ko ṣe ohun to yẹ lati mu orileede yii tẹsiwaju - Ọjọgbọn Salami


Oludamọran pataki fun Aarẹ Buhari lori eto eto ọrọ aje, Ọjọgbọn Doyin Salami ti sọ pe gbogbo awọn to n ṣakoso orileede Naijiria ko ṣe awọn ohun to yẹ lati mu itẹsiwaju ba ilẹ yii.
 
Ọjọgbọn Salami lo sọrọ yii nibi eto idanilẹkọọ ọlọdọọdun ti Ṣobọ Ṣowẹmimọ, ti ọdun 2023 to waye ni Abẹokuta Club, Abẹokuta, ipinlẹ Ogun lọjọ Aiku, Sannde to kọja yii.
 
Nibẹ lo ti sọ pe orileede Naijiria ni awọn amuyẹ to le fi ni itẹsiwaju ati idagbasoke, ṣugbọn ti awọn adari to n ṣakoso ko mojuto bo ṣe yẹ.
 
O ni kaka ki awọn adari ṣe ohun ti yoo mu oileede yii tẹsiwaju, niṣe ni wọn n mọn-ọn mọ ṣakoso bo ṣe wu wọn lai bikita.
 
Nigba to n ṣe idanilẹkọọ lori akori to pe ni "Imperatives of Nigeria's Regeneration", ninu gbọngan Alake, o ni Naijiria ko le farada ki nnkan kan maa ṣẹlẹ bo ṣe wu.

"Naijiria ko tii gbe igbesẹ akin lati fi mu itẹsiwaju ba, nnkan kan n ṣẹlẹ ni. A ko tii mu ki nnkan ṣẹlẹ. Ṣugbọn Naijiria lasiko yii, a ko le fara mọ ki nnkan kan maa ṣẹlẹ. A ni lati gbe igbesẹ ti yoo mu itẹsiwaju wa."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI