Oogun owo ni mo fẹẹ fi ori oku ati apa meji ṣe - Gbajumọ Aafa tọwọ tẹ n'Ibadan jẹwọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 13, 2023

Oogun owo ni mo fẹẹ fi ori oku ati apa meji ṣe - Gbajumọ Aafa tọwọ tẹ n'Ibadan jẹwọ


Ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti tẹ gbajugbaja Aafa ẹni ọdun marundinlaadọta nni, Hassan Kọlawọle pẹlu ori oku tutu ati apa meji nigboro ilu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa lo foju Kọlawọle han ni olu-ileeṣẹ wọn to wa ni Ẹlẹyẹle niluu Ibadan laipẹ yii, lakoko ti wọn n foju awọn ọdaran tọwọ tẹ han.

Ọjọ kẹfa, oṣu kọkanla, ọdun ti a wa yii ni agbẹnusọ ọlọpaa, Adebọla Hamzat sọ f'awọn akọroyin pe ọwọ tẹ Hassan pẹlu awọn ẹya ara oku eeyan naa.
 
Lara awọn nnkan miran to sọ pe awọn tun gba lọwọ Hassan ni ẹrọ kọmputa alagbeka kan to fi n ṣiṣẹ.

Hamzat sọ pe agbegbe ti wọn n pe ni Ọgbẹrẹ-ti-o-ya to wa nijọba ibilẹ Ọna Ara lọwọ ti tẹ Hassan lọjọ naa.

Nigba toun funra rẹ n jẹwọ, Hassan sọ pe oogun owo loun fẹẹ fi ori ati apa eeyan meji ti wọnn ka mọ oun lọwọ ṣe, nitori boun ṣe n la ipenija airijẹ kọja.
 
“Iyawo kan ati ọmọ meji ni mo ni, o si ṣoro fun mi lati tọju wọn daadaa bo ṣe wu mi.
 
“Nibi ti mo ti n wa ọna lati la kaakiri ni mo ti pade Waheed, ẹni toun naa jẹ Aafa ni Maolud. A jọ sọrọ titi, o si jẹ ki n mọ wi pe oun mọ nipa oogun owo ti yoo si nilo ẹya ara eeyan.

“Mo jẹ ko mọ pe mi o mọ bi mo ṣe maa ri ẹya ara eeyan, o si ni ki n ma da ara mi laamu, oun yoo ba mi wa wọn.

“Funra rẹ lo pada gbe awọn ẹya ara naa wa fun mi ni Amukoko, nibi ti a ti pade laarọ kutu, mo si tọju wọn sinu ọfiisi mi, nibi ti mo ti maa n da awọn eeyan lohun fun iṣoro ti wọn ba ni.

“Awọn ọlọpaa lo pada wa yẹ ọfiisi mi wo lọjọ ti mo gba awọn ẹya ara oku eeyan naa.”

Hassan sọ pe ẹni to gbe ẹya ara naa foun ti juba ehoro, nitori ti wọn ko le sọ pato ibi to wa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI