Baale ile, ẹni ọdun mẹrinlelogoji kan, Ọlanrewaju Kọlawọle ti ṣalaye wi pe inu ṣọọṣi loun ti pade iyawo oun, ṣugbọn toun ko mọ pe ogbologbo alaṣẹwo ni.
Kọlawọle ati iyawo rẹ ni wọn lọ sori eto Kọkọrọ Alatẹ ti gbajugbaja sọrọsọrọ niluu Ibadan, Oriyọmi Hamzat, nibi ti aṣiri ti tu wi pe oun kọ loun ni awọn ọmọ mẹrin ti iyawo oun bi f'oun.
Ori redio naa ni Kọlawọle ti rawọ ẹbẹ s'awọn ọmọ Naijiria lori ohun to le ṣe pẹlu bi ayẹwo ẹjẹ ṣe sọ pe oun kọ loun ni awọn ọmọ mẹrin ti iyawo oun gbe foun lati ọdun mẹrindinlogun seyin.
Kọlawọle, ọmọ bibi ilu Ikire to wa nijọba ibilẹ Irewọle, ipinlẹ Ọṣun sọ peayẹwo DNA toun lọ ṣe fun awọn ọmọ mẹrin toun n pe lọmọ oun tipe ni wọn kii ṣe ọmọ oun.
Ọdun 2007 ni Kọlawọle ati iyawo ẹ, Toyin Tẹlla ṣegbeyawo, ti obinrin naa si bimọ mẹrin to gbe fun ọkọ re pe oun lo ni wọn.
Nigba to n sọrọ, o ni
“Mo fẹ k'awọn ọmọ Naijiria gba mi, nitori pe iyawo yii ko gbọdọ jẹ mi gbe. Ọdun 2007 la ṣegbeyawo ti a si bimọ mẹrin.
“
Ọmọ mẹrin lo bi, ṣugbọn ko si eyikeyi to jẹ temi ninu wọn lẹyin ayẹwo ẹjẹ ti mo lọ ṣe.”
Tella Toyin, nigba toun naa n sọrọ sọ pe oun ko gba ayẹwo naa, nitori pe o ṣee ṣe ko jẹ irọ ni.
O loun ko si nibẹ nigba ti wọn n gba ẹjẹ awọn ọmọ naa, toun ko si mọ ẹjẹ ti wọn gba.
“Mi o gba esi ayẹwo naa. Mi o gba nitori pe mi o si nibẹ nigba ti wọn n gba ẹjẹ, mi o si mọ eyi ti wọn gba, fun idi eyi, mi o gba. Mi o gba nitori pe mo mọ bi mo ṣe bi gbogbo wọn.”
No comments:
Post a Comment