Ijọba Kwara kẹyin s'awọn to n tọrọ baara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, November 30, 2023

Ijọba Kwara kẹyin s'awọn to n tọrọ baara


Ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ pe awọn ti kẹyin patapata ti gbogbo awọn to n tọrọ baara l'awọn oju popona ati agbegbe to fi mọ igberiko to wa nipinlẹ naa.
 
Ijọba sọ pe gbogbo awọn to n tọrọ baara kaakiri yii ni wọn n doju ti ipinlẹ naa kaakiri, pẹlu iwa i ko bojumu naa.
  
Kọmiṣanna fọrọ idagbasoke ọmọniyan, Social Development nipinlẹ naa, Ọnarebu Ọpẹyẹmi Oluwakẹmi Afọlaṣade lo eyi di mimọ lasiko ti wọn n pari lile awọn to n tọrọ baara naa kuro.

Ọnarebu Afọlaṣhade sọ pe gbogbo awọn to n tọrọ baara ọhun ni wọn n fi ojoojumọ pọ si, ti ko si sẹni ti wọn ko le tọrọ owo lọwọ rẹ, eyi to ni iwa naa ko bojumu to laaarin ilu to n fẹ ilọsiwaju.

Siwaju sii lo sọ pe awọn miran maa n lo anfaani ipenija kekere ti wọn ni  lati maa fi tọrọ baara kiri, dipo ki wọn wa iṣẹ ti wọon yoo ṣe.
 
O wa l'awọn ko ni gba iwa naa mọ laarin igboro ati igberiko to wa nipinlẹ naa, ati pe ẹni ti ọwọ ba tẹ yoo ki ọwọ abamọ bọ ẹnu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI