Gbogbo eto lo ti fẹẹ pari bayii fun gbajugbaja olorin Fuji nni, Alaaji Saheed Oṣupa lati dalu bolẹ nibi ayẹyẹ ọdun Ifa to fẹẹ waye niluu Arigbajo, Ifọ, ipinlẹ Ogun.
Ọjọ kẹsan, oṣu kejila, ọdun ti a wa yii (2023) ni Saheed Oṣupa ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Ọba Orin pẹlu ilu-mọ-ọn-ka Tọpẹ Nautical yoo fi orin da awọn alejo lọla.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Oloye Ifayọmi Babatunde ti ọpọ mọ si Ọba Edu lo fẹẹ ṣayẹyẹ ọdun Ifa rẹ niluu Arigbajo lati ọjọ keje si ọjọ kẹsan, oṣu kejila ọdun yii si ni.
Igba kẹsan ree ti ayẹyẹ ọdun Ifa naa ti Ọba Edu n ṣagbatẹru rẹ yoo maa waye.
Gbogbo ilu Arigbajo Ifọ ni yoo mi titi lọjọ naa pẹlu bi Ọba Orin ati Tọpẹ Nautical yoo ṣe fi orin da awọn eeyan laraya lọjọ naa.
Fun ibeere tabi alaye lẹkunrẹrẹ, anfaani wa lati pe 08020587706.
No comments:
Post a Comment