Imọ ẹrọ igbalode: Kwara tọwọ bọwe adehun ajọṣepọ pẹlu ileeṣẹ IHS Towers - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, November 19, 2023

Imọ ẹrọ igbalode: Kwara tọwọ bọwe adehun ajọṣepọ pẹlu ileeṣẹ IHS Towers


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti tọwọ bọwe adehun lori ajọṣepọ pẹlu gbajugbaja ileeṣẹ imọ ẹrọ igbalode ti a mọ si IHS Tower lori idasgbasoke eto imọ-ẹrọ ati tẹkinọlọji, to fi mọ iṣẹ ọwọ fun ilọsiwaju eto ọrọ aje.
 
Iwe adehun naa ni lati tun mu gbagede Ilorin Innovation Hub gbooro si, ki wọn le ṣe aṣeyọri lori koko pataki ti wọn fi da a silẹ.

Nigba to n sọrọ nibi titọwọ bọwe adehun naa lọjọ Satide to kọja, Gomina AbdulRazaq sọ pe iwe adehun naa jẹ ti ala rere to wa si imuṣẹ.
 
Alakoso ati oludasilẹ IHS Towers naa, Mohammed Darwish ko gbẹyin nibi ajọsọ ọhun.

Ninu ọrọ gomina siwaju sii lo sọ pe oun nigbagbọ wi pe ipinnu awọn lori idagbasoke ati itẹsiwaju eto imọ ẹrọ igbalode nipinlẹ naa yoo wa si imuṣẹ pẹlu ileeṣẹ ti wọn ba dowo pọ.

Temi Kọlawọle to jẹ alakoso Innovation Hub nipinlẹ naa sọ pe ajọṣepọ tuntun yii yoo mu ki iṣẹ pọ lọpọ yanturu fun awọn ọdọ, paapaa awọn to fẹ maa fi imọ ẹrọ igbalode jẹun.
 
O ni awọn ọdọ yoo mu anfaani ọhun lo nipinlẹ Kwara, nipa bi ba ẹgbẹ pe kaakiri agbaye.

Bakan naa lo fi da awọn eeyan loju wi pe Ileeṣẹ Ilorin Innovation Hub yoo tọwọ bọwe adehun pẹlu ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri sọrọ ikansira-ẹni ati imọ ẹrọ, Federal Ministry of Communications Innovation and Digital Economy lori oriṣiriṣi eto, ati pe ileeṣẹ IHS Towers naa yoo pẹlu.

Darwish ninu ọrọ tiẹ gbe oṣuba kare fun Gomina ipinlẹ Kwara lori ipa to n ko nipa idagbasoke imọ ẹrọ ti ko fi ṣẹrẹ, to si lawọn yoo ri daju pe wọn tukọ eto ọhun bo ti tọ ati bo ti yẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI