Irọ to jina si otitọ ni pe Gomina AbdulRazaq da Emir Tsaragi duro fun oṣu mẹfa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, November 19, 2023

Irọ to jina si otitọ ni pe Gomina AbdulRazaq da Emir Tsaragi duro fun oṣu mẹfa


Ijọba ipinlẹ Kwara ti pariwo sita wi pe irọ to jinna ti otitọ ni pe Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti da Emir tiluu Tsaragi, Alayeluwa Alaaji Aliyu Abdullahi duro fun oṣu mẹfa gbako.

Ninu atẹjade ti Kọmiṣanna fọrọ eto ijọba ibilẹ ati oye jijẹ nipinlẹ naa, Ọnarebu Abdullahi Abubakar Bata fi sita lọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii lo ti sọ pe ayederu iroyin ni awọn kan n gbe kaakiri ori ayelujara, to si ni ko yẹ ko ri bẹẹ.

"Wọn ti ta ijọba Kwara lolobo nipa ayederu iroyin abanilorukọjẹ kan wi pe Gomina ipinlẹ Kwara, Mallam AbdulRahman AbdulRazaq (CON) ti sọ pe ki Ẹmi tiluu Tsaragi, Alaaji Aliyu Abdullahi lọ rọkun nile fun oṣu mẹfa gbako.

"A fẹẹ sọ ọ sita gbangba wi pe irọ to jinna si otitọ patapata ni, leyi ti awọn to kọ ọ ati awọn to n gbero lati ba ijọba lorukọ jẹ n gbe kaakiri, paapaa lati da wahala silẹ laarin ijọba ati ẹgbẹ awọn ọba alaye nipinlẹ naa. Ipinnu yii ti ku ko too jade.

"Ijọba to wa nita lasiko yii ti fi han daju pe ohun bọwọ pupọ fun awọn ọba alaye nipinlẹ naa. Eyi yoo si wa bẹẹ nipa ilana Gomina AbdulRazaq, ẹni to bọwọ fun aṣa ati iṣe awọn araalu."
 
Bakan naa lo rọ araalu lati dẹkun gbigba ayederu iroyin to ba n kaakiri agbegbe wọn gbọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI