Kwara: Igbesẹ bẹrẹ lati dẹkun iwa ibajẹ t'awọn 'bola-bola' n hu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 13, 2023

Kwara: Igbesẹ bẹrẹ lati dẹkun iwa ibajẹ t'awọn 'bola-bola' n hu


Ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ pe awọn ti bẹrẹ igbesẹ lati dẹkun iwa buruku ti awọn adigunjale ti wọn n fi iṣẹ 'bola-bola', iyẹn awọn to n ṣa irin kaakiri adugbo n hu.
 
Kọmiṣanna fọrọ eto ayika, Malaamu Shehu Ndanusa Usan lo sọ eyi di mimọ lasiko ipade to ṣe pẹlu awọn adari ẹgbẹ to n ṣa irin kaakiri naa niluu Ilọrin.

Nigba to n sọrọ, o ni iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ko gba ti iwa ti awọn to n ṣa irin kaakiri naa n hu, nitori pe niṣe lo n ṣakoba fun eto aabo.
 
O ni ileeṣẹ eto ayika naa ti wa dide lati dẹkun iwa  ati iṣẹ ti wọn n ṣe kaakiri ipinlẹ naa lati rii pe ẹmi ati dukia awọn araalu ko si ninu ewu.

Siwaju sii lo sọ pe wọn yoo bẹrẹ sii forukọsilẹ ko to di pe wọn bẹrẹ iṣẹ wọn, ati pe wọn yoo gba nọmba idanimọ ti a mọ si 'code', bẹẹ si ni wọn yoo maa wọ aṣọ idanimọ ni gbogbo igba ti wọn ba wa lẹnu iṣẹ.
 
Ṣaaju ninu ọrọ rẹ, alaga ẹgbẹ awọn to n ṣa irin nipinlẹ naa, Mallam Musa Umah dupẹ ribiribi lọwọ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq fun awọn eto ọkan-o-jọkan to n mu iwuri ba awọn araalu.
 
Bẹẹ lo sọ pe awọn ṣetan lati tẹle ilana ati ofin ti ijọba ba fi silẹ lati fi ṣiṣẹ wọn, nitori pe awọn kii ṣe ọdaran.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI