Iwadii bẹrẹ lori ọkunrin ti wọn yinbọn fun ni Ṣagamu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 13, 2023

Iwadii bẹrẹ lori ọkunrin ti wọn yinbọn fun ni Ṣagamu


Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun fi n sọ pe awọn ti bẹrẹ iwadii ni kikun lati mọ awọn to yinbọn pa ọkunrin kan ladugbo Ewusi to wa nitosi ikorita Ita Ọba, Sagamu, ipinlẹ Ogun.
 
Ọjọ kẹwaa, oṣu kọkanla, ọdun 2023 ni wọn sọ pe awọn kan kan lori ọkada yinbọn pa ọkunrin naa, ti wọn si juba ehoro.
 
Loju ẹsẹ ni wọn sọ pe ọkunrin naa dagbere faye.
 
Iro ibọn ti wọn l'awọn ara agbegbe yii gbọ, lo jẹ ki onikaluku wọn sa asala fun ẹmi ara wọn.
 
Nigba o n sọrọ, agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Ọmọlọla Odutọla ṣalaye pe awọn ọlọpaa to n ṣiṣẹ kọja lọ lo ṣalabapade oku ọkunrin naa nibi ti wọn pa a si.
 
O ni awọn ọlọpaa naa ni wọn gbe oku wọn lọ si mọṣuari.

Siwaju sii lo fi kun ọrọ rẹ pe wọn ba apa ibọn ni ọrun, ikun ati apa rẹ, leyi ti ko jẹ ko ye e, ati pe awọn tun ba ọta ibọn mẹta layika rẹ.
 
O sọ pe ọga awọn, Abiọdun Alamutu ti paṣẹ pe ki iwadii bẹrẹ lẹkunrẹrẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI