Mo gbiyanju agbara mi lati mu orileede de ilẹ ileri, ṣugbọn awọn ọmọ Naijiria ṣoro lati dari - Buhari sọrọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, November 21, 2023

Mo gbiyanju agbara mi lati mu orileede de ilẹ ileri, ṣugbọn awọn ọmọ Naijiria ṣoro lati dari - Buhari sọrọ


Aarẹ ana lorileede Naijiria, Muhammadu Buhari ti sọ pe oun biyanju gbogbo agbara oun lati mu orileede yii de ilẹ ileri, ṣubọn to sọ pe awọn ọmọ ilẹ yii ṣoro lati dari wọn.
 
Buhari lo sọrọ naa lori ẹrọ amohunmaworan Naijiria, Nigerian Television Authority, NTA fun igba akọkọ latigba to ti gbe ijọba silẹ lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun, ọdun 2023.
 
O ni laisko toun wa nijọba, oun gbiyanju gbogbo agbara oun lati rii pe awọn araalu jẹ mudunmudun iṣejọba awarawa, ṣugbọn to ni awọn araalu ko gba foun.
 
Buhari tẹsiwaju pe boya oun ṣe daadaa, tabi oun ko ṣe daadaa to, o ku si awọn araalu lọwọ lati sọ tẹnu wọn.
 
“Ọlọrun fun mi ni anfaani lati sin orileede mi, ṣugbọn mo sa ipa mi. Boya ipa ti mo sa wa dara tabi ko dara, mo fi silẹ fun awọn eeyan lati dajọ.
 
“Awọn ọmọ Naijiria ṣoro pupọ. Awọn eeyan mọ ẹtọ wọn. Wọn ro pe awọn lo yẹ ki wọn wa nibẹ, kii ṣe iwọ.
 
“Fun idi eyi, gbobo igbesẹ ni wọn n ṣọ. Ẹ si ni lati lakaka lati rii pe ẹ ṣe ohun to yẹ lati ṣe.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI