Gomina AbdulRazaq ṣabẹwo si akanṣe iṣẹ ilu to n lọ lọwọ niluu Igbaja, Ọra - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, November 21, 2023

Gomina AbdulRazaq ṣabẹwo si akanṣe iṣẹ ilu to n lọ lọwọ niluu Igbaja, Ọra


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ti ṣabẹwo siluu Igbaja ati Ọra lati bojuto ibi ti iṣẹ de duro lori awọn akanṣe iṣẹ idagbasoke to n lọ lọwọ.
 
Aarin gubngbun ipinlẹ Kwara ni awọn ilu mejeeji yii wa.

Nibi abẹwo naa ni gomina ti ṣeleri fun awọn araalu nipa igbe aye irọrun ati eto aabo to pe ye.

O ni gbogbo agbegbe pata to wa ni ijọba ibilẹ kọọkan ni iṣakoso oun yoo ti ṣiṣẹ idagbasoke fun ilọsiwaju eto ọrọ aje araalu ati ijọba lapapọ.
 
Awọn araalu naa wa gbe oṣuba kare fun gomina lori awọn iṣẹ idagbasoke to n ṣe lagbegbe wọn loore-koore.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI