OGUN 2023: Ile-ẹjọ da Dapọ Abiọdun lare, o doju Adebutu bọle l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, November 25, 2023

OGUN 2023: Ile-ẹjọ da Dapọ Abiọdun lare, o doju Adebutu bọle l'Ogun


Ile-ẹjọ kotẹmilọrun to n gbọ ẹjọ idibo gomina ipinlẹ Ogun ti sọ pe Gomina Dapọ Abiọdun ni ojulowo gomina ti awọn araalu dibo yan ninu ẹtọ idibo gomina to waye lọjọ kejidinlogun, oṣu kẹta, ọdun 2023.

Ọjọ Ẹti, Friade, ọsẹ yii ni awọn Onidajọ meji nile-ẹjọ naa, J. S Ikyegh ati Muhammed Mustapha sọ pe ko si awijare kankan ninu ẹjọ ti oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party (PDP), Ọnarebu Ladi Adebutu pe lati tako ibo to gbe Dapọ wọle.

Ṣaaju,  lọgbọn ọjọ, oṣu kẹsan, ọdun yii ni ile ẹjọ Tribunal ti kọkọ da Dapọ Abiọun lare. 

Idajọ naa ni ko tẹ Adebutu lọrun, to fi gba ile ẹjọ kotẹmilọrun lọ l'Ekoo, ṣugbọn ti nnkan ko pada ṣe ẹnu rere.

Ile ẹjọ naa sọ pe awọn ẹsun ti Adebutu fi kan Abiọdun nile ẹjọ ko l'ẹsẹ nilẹ, nitori pe ko si ẹri kikun, ati pe awọn ẹlẹri ko ni awijare gidi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI