Ṣọọṣi Genesis Global fẹẹ mi ilu Eko ati agbegbe rẹ titi pẹlu akanṣe Ajọdun Ikore - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, November 19, 2023

Ṣọọṣi Genesis Global fẹẹ mi ilu Eko ati agbegbe rẹ titi pẹlu akanṣe Ajọdun Ikore


Ko si iroyin meji to n lọ kaakiri igboro lasiko yii to kọja gbajugbaja ṣọọṣi sẹlẹ nni, Celestial Church of Christ, ẹka ti Genesis Global to wa ladugbo Duro Ishola, Dalemọ-Alakukọ nipinlẹ Ekoo to kọja akanṣe ajọdun Ikore to fẹẹ waye ninu oṣu kejila, ọdun ti a wa yii.
 
Akanṣe eto ọhun ti wọn pe akori rẹ ni Harvest of Strange Favour ni yoo bẹrẹ pẹlu aṣalẹ orin iyin (Praise Night) lọjọ kẹẹdogun, oṣu kejila, ọdun 2023.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọjọ mẹta gbako ni eto ajọdun Ikore naa yoo fi waye ninu ijọ ọhun ti Wolii Israel Ọladele Ogundipẹ jẹ alakoso rẹ.

Ọjọ kẹẹdogun, oṣu kejila ti aṣalẹ orin iyin (Praise Night) yoo waye, bẹrẹ ni deedee agogo mẹjọ alẹ titi ti ilẹ yoo fi mọ si ọjọ kerindinlogun.

Hallel Night of Praise ni wọn pe akori aṣalẹ orin iyin ọhun, nibi ti awọn gbajugbaja olorin ẹmi bii Bukọla Ittah, Moji Daramọla, Apekẹọla, Dare Oxygen, ati Oluwaṣẹgunfunmi 02 yoo ti fi orin ẹmi da awọn eeyan lara ya.


Awọn olorin ẹmi miran ti yoo wa nibẹ ni Engo, Bidemi Ọlaọba, Rain ati Moses Harmony.

Iyẹn nikan tun kọ, awọn ti ko ba lanfaani lati wa nibẹ yoo ri bi nnkan ṣe n lọ lori ikanni ayelujara ti ṣọọṣi Genesis Global lori YouTube, Facebook, Instagram, TikTok ati bẹẹ bẹẹ lọ.
 
Aṣalẹ naa ni Wolii Israel Ọladele Ogundipẹ yoo tun ti paṣẹ asọtẹlẹ iyanu sinu aye awọn eeyan, ti awọn ogun ọrun yoo si fi aṣẹ sii loju ẹsẹ.

Pabambari rẹ ni ti ọjọ Ajọdun Ikore ti yoo waye lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kejila, ọdun 2023, nibi ti awọn olorin ẹmi ọhun ko tun ti ni gbẹyin lati kọrin.
 
Awọn ẹmi ọrun, iyẹn awọn Angẹli yoo sọkalẹ ni gbogbo ọjọ mẹtẹẹta lati ṣe iṣẹ iyanu, ti awọn eeyan yoo si maa gba ibukun ara-ọtọ ti ko wọpọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI