Adron Homes, ileeṣẹ to n sọ ile gbigbe di irọrun f'awọn mẹkunnu Naijiria - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, November 19, 2023

Adron Homes, ileeṣẹ to n sọ ile gbigbe di irọrun f'awọn mẹkunnu Naijiria


Pupọ awọn ọmọ Naijiria ti wọn ti jẹ anfaani ti wọpọ nileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited ni wọn n fi adura ranṣẹ si awọn alakoso ati oludasilẹ ileeṣẹ naa.
 
Odu ni ileeṣẹ Adron Homes jẹ, kii ṣaimọ foloko nipa ọrọ ile gbigbe ati ilẹ lorileede Naijiria, ti wọn si ti lo iwa oju aanu wọn ṣe araalu lore.
 
Ọpọ ti ko lero wi pe awọn yoo ra ilẹ, depodepo wi pe wọn yoo di onile lori lo ti n dabi ala fun wọn bayii, pẹlu bi ileeṣẹ Adron Homes ṣe mu wọn kuro ninu ẹgbẹ ayalegbe bọ si ẹgbẹ lanlọọdu.
 
Gbogbo ibi ti Adron Homes ti ni ilẹ kaakiri Naijiria bii Ekoo, Nassarawa, Abuja, Ekiti, Ọyọ, ati Ogun ni awọn araalu ti n jẹ anfaani ti ko wọpọ yii.

Owo ti ileeṣẹ Adron Homes n ta ilẹ ati dukia wọn dinku patapata si eyi ti awọn ileeṣẹ miran n ta ti wọn, paapaa lasiko ọwọngogo to wa nita bayii.


Awọn agbegbe to dun n wo, ti wọn si jọju ni ileeṣẹ Adron Homes ti n ta dukia ati ilẹ f'awọn araalu, paapaa bii Victoria Island, Ikoyi, ati Lekki, nipinlẹ Ekoo.

Lara awọn anfaani ti awọn alakoso ileeṣẹ naa gbe kalẹ ni sisan owo diẹdiẹ lọna ti ko ga ni lara, yiyọ ida iye owo ti awọn oloyinbo n pe ni percentage kuro ati bẹẹbẹẹlọ.
 
Gbogbo awọn iwe aṣẹ to yẹ lori ilẹ ati dukia ni ileeṣẹ yii yoo tun ko kalẹ fun awọn onibara wọn, ti yoo si fọkan wọn balẹ lọjọ iwaju.
 
Njẹ iwọ naa n wa ọna lati di onile lori lai laagun jinna lọna irọrun, ki o si le ifọkanbalẹ ọjọ alẹ, tete kan si eyikeyi ileeṣẹ Adron Homes to wa nitosi rẹ lati beere ibeere to ba wa si ọ lọkan fun aridaju.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI