Wo awọn afaani to wa ninu 'Lemon Friday' ti ileeṣẹ Adron Homes gbe kalẹ fun araalu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, November 22, 2023

Wo awọn afaani to wa ninu 'Lemon Friday' ti ileeṣẹ Adron Homes gbe kalẹ fun araalu


Ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited to n ṣowo ilẹ ati dukia lorileede Naijiria ti gbe anfaani ọtun sita fun irọrun araalu, bi ọdun 2023 ṣe n pari lọ.

Gbogbo eeyan lo mọ pe eto 'Black Friday lo lokiki julọ ti awọn ileeṣẹ ati ile itaja igbalode maa n ṣe fun araalu lati fi mu adinku ba iye ti wọn n ta ọja wọn.
 
Ṣugbọn ni ti ileeṣẹ Adron Homes, 'Lemon Friday' ni wọn pe anfaani ọtun ti wọn ti wọn ṣẹṣẹ gbe jade sita, fun irọrun ati igbadun araalu, paapaa awọn to n foju sọna lati di onile lori.
 
Bi wọn ba n darukọ awọn ileeṣẹ to n ta ilẹ ati ile lorileede Naijiria lasiko yii, ọkan pataki ni ileeṣẹ Adron Homes to jẹ ti gbajugbaja nni, Aarẹ Adetọla Emmanuelking jẹ, kii ṣaimọ foloko.
 
Lọpọ igba si ni ileeṣẹ Adron Homes maa n gbe iru awọn anfaani ti ko wọpọ bayii kalẹ fun igbadun araalu ati lati sọ awọn eeyan di onile lori.

Ni bayii, bi ọdun 2023 ṣe n pari lọ, Ileeṣẹ Adron Homes ti sọ ọ sita gbangba wi pe ki awọn eeyan le tete bọ kuro ninu ẹgbẹ ayalegbe, awọn yoo ja owo awọn ilẹ wọn wa silẹ.

Iyẹn ni pe adinku yoo ba iye ti wọn n ta awọn ilẹ lawọn agbegbe ti wọn ni ilẹ si kaakiri Naijiria.

Yatọ si eyi, anfaani sisan owo diẹdiẹ tun ti wa fun awọn ti ko ba le san owo lẹẹkan ṣoṣo.

Nigba ti awọn alakoso naa n sọrọ laipẹ yii nibi ipade awọn akọroyin ti wọn ṣe kọja, wọn sọ pe awọn onibara tun le bẹrẹ sisan owo ilẹ wọn pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira, bẹẹ si ni wọn yoo tun ni anfaani si awọn ẹbun bii baagi irẹsi, adiẹ ati awọn nnkan miran lati fi ṣayẹyẹ ọdun.
 
Bakan naa, awọn to ba tun bẹrẹ sisan ẹgbẹrun lọna ọgọta naira yoo ni anfaani si Irẹsi baagi kan, Ororo, Ẹrọ ijata igbalode inu ile, faanu ati ohun idana to n lo ina mọnamọna.

Awọn onibara tun le san ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira lati jẹ oriṣiriṣi ẹbun to wa nibẹ.

Bi owo ti onibara ba ṣe san fun igba akọkọ ba ṣe pọ to naa ni iye ẹbun ti wọn yoo gba yoo ṣe pọ to, lo mu ko jẹ pe bi onibara ba san ẹgbẹrun lọna igba naira, yoo gba agbo ọdun, baagi irẹsi, faanu ati awọn nnkan miran.

Fun awọn to ba san idaji miliọnu naira, wọn yoo gba firiiji, agbo, maṣiini ifọṣọ igbalode, maṣiini idana igbalode ati baagi irẹsi kan.
 
Awọn onibara lanfaani lati mu eyikeyi anfaani ti wọn ba ro pe o tọ si wọn si, ki wọn si le gba ẹtọ ti yoo ba wa pẹlu rẹ.
 
Anfaani yii lo ṣi silẹ ninu oṣu kọkanla titi di oṣu ọsẹ akọkọ ninu oṣu kejila, ọdun 2023.
 
Fun ibeere tabi alaye lẹkunrẹrẹ, ẹ kan si awọn alakoso ileeṣẹ naa lori awọn ikanni wọnyi Facebook Adronhomesofficial, Twitter @adronhomes and Instagram @adronhomesofficial tabi ikanni ayelujara www.adronhomesproperties.com.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI