Ọpọ awọn ti wọn ko kọ iṣẹ iroyin ni wọn n ba iṣẹ akọroyin jẹ ni Naijiria - Ọmọwe Adeyẹmọ sọrọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, November 22, 2023

Ọpọ awọn ti wọn ko kọ iṣẹ iroyin ni wọn n ba iṣẹ akọroyin jẹ ni Naijiria - Ọmọwe Adeyẹmọ sọrọ


Gbajugbaja akọroyin to tun jẹ alakoso ileeṣẹ to n ri sọrọ ilẹ ati ile kikọ n'ipinlẹ Ogun, Ọmọwe Babatunde Adeyẹmọ ti rọẹgbẹ awọn ojulowo akọroyin lorileede Naijiria lati dide gbogun ti awọn to n ba iṣẹ naa jẹ.

Ọmọwe Adeyẹmọ lo parọwa yii lọjọ Iṣẹgun, Tuside nibi ayajọ ọjọ tẹlifiṣan lagbaye ti ẹka ẹgbẹ awọn akọroyin ti wọn pe ni Consolidated Chapel nipinlẹ Ogun ṣagbakalẹ rẹ niluu Abẹokuta.
 
Nibẹ lo ti sọ pe pupọ awọn ti wọn ko mọ nipa iṣẹ iroyin ni wọn fẹẹ dabaru orileede Naijiria nipa awọn ayederu iroyin ti wọn n gbe kaakiri, pẹlu erongba lati fi pawo sapo ara wọn.

O ni bo ṣe jẹ ọpọ araalu lo ti di akọroyin ojiji nipa wi pe ki aye le mọ wọn lai kọṣẹmọṣẹ, ti wọn ko si lọ sile-ẹkọ lati mọ pataki ojulowo iroyin ati akoba ti iroyin ẹlẹjẹ le ṣe, akoba nla lo n ṣe fun idagbasoke orileede yii.

Siwaju sii lo rọ awọn ọjọgbọn lẹka iṣẹ iroyin lati dide gbe igbesẹ lati gba iṣẹ naa kuro lọwọ awọn alaimọkan ti wọn n gba iṣẹ naa ṣe fun ifẹ, iṣọkan ati alaafia orileede yii.

Alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Pelican Valley Nigeria Limited, ẹni to ti figba kan ri jẹ oṣiṣẹ-kọroyin ileeṣẹ MITV naa tun sọ siwaju pe bi a ko ba fẹ ki ogun ṣẹlẹ, a fi ki a gbogun ti ayederu iroyin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI