Awọn ọlọpaa to n tọrọ owo lọwọ ọlọkada ti n fi ẹnu fẹra bi abẹbẹ lahamọ - Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, December 10, 2023

Awọn ọlọpaa to n tọrọ owo lọwọ ọlọkada ti n fi ẹnu fẹra bi abẹbẹ lahamọ - Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria


Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti sọ pe awọn ọlọpaa meji kan ti wọn n tọrọ owo lọwọ ọlọkada igbalode to wa lati Dutch ninu fọnran kan to wa lori ayelujara ti wa lahamọ.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ wọn, Olumuyiwa Adejọbi fi sita lo ti sọ pe iwa ibajẹ to n doju ti iṣẹ ọlọpaa lawọn mejeeji hu, to si lawọn ko le gboju fo o da.

Adéjọbí sọ pe agbegbe Ojongbodu to wa loju ọna Isẹyin si Ogbomọṣọ ni awọn ọlọpaa ọhun ti da obinrin ọlọkada igbalode naa duro, ti wọn si n tọrọ owo lọwọ rẹ.


O ni awọn mejeeji yii ni wọn ti wa lahamọ nibi ti wọn ti n fi ẹnu fẹra bi abẹbẹ, nitori pe wọn ni lati sọ ohun ti wọn ri lọbẹ, ti wọn fi waaru ọwọ.

Bakan naa lọ sọ pe ọga ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Adebọla Ayinde Hamzat ti gbe igbimọ oluwadii dide lati fiya jẹ awọn mejeeji yii lọna to tọ.


Bẹẹ lo fi kun ọrọ rẹ pe ọga ọlọpaa ẹkun ti awọn mejeeji naa wa yoo jẹ iyan rẹ niṣu pẹlu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI