Tirela pa ọlọkada danu l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, December 10, 2023

Tirela pa ọlọkada danu l'Ogun


Ariwo ikunlẹ abiyamọ lo gba ẹnu awọn ara agbegbe Alagbọn si Ọlọrunda to wa loju ọna Owode-Idiroko, ipinlẹ Ogun lọjọ Ẹti to kọja.

Ninu atẹjade ti alakoso ẹkun Guusu-Iwọ-Oorun fun ileeṣẹ alaabo oju popo ti TRACE, Adekunle Ajibade fi sita, o ni ere asapajude ti tirela kan ti ko ni nọmba idanimọ n sa lo ṣakoba.

Ajibade sọ pe nnkan bi agogo mẹrin kọja iṣẹju mẹẹdogun irọlẹ ni tirela Mercedes-Benz ọhun gba ọlọkada Bajaj ti nọmba idanimọ rẹ jẹ DGB 504 VK .

O ni inu odo to wa ni afara Alagbọn-Ọlọrunda ni tirela ọhun gba ọlọkada yii si, tiyẹn si gbabẹ sọda sọrun alakeji.

Siwaju sii lo fidi rẹ mulẹ pe awọn mẹrin lo wa ninu ijamba yii nigba ti ori ko awọn meji yọ, ti ẹnikan farapa, ti ẹnikan yooku si gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI