Awọn oṣiṣẹ Kwara gba owo oṣu kejila lati tete ra nnkan fun ayẹyẹ ọdun Keresimesi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, December 22, 2023

Awọn oṣiṣẹ Kwara gba owo oṣu kejila lati tete ra nnkan fun ayẹyẹ ọdun Keresimesi


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti buwọ lu sisan owo oṣu kejila fun gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba patapata.

Eyi ni lati pe jẹ ki awọn eeyan tete lọ ra awọn nnkan ti wọn yoo fi ṣọdun Keresimesi to wọle de ati ọdun tuntun yo n bọ lọna.

Gomina AbdulRazaq sọ pe ko digba ti oṣu ba pari ko to di pe awọn oṣiṣẹ gba ẹtọ wọn, ti yoo si mu ki wọn naa sare kaakiri lati ra nnkan ọdun.

O ni gbogbo araalu gbọdọ ni imọlara ipa rere ti ijọba nko.

1 comment:

  1. Thought our governor really try but we are just appealling to him to pay our two months palliative so as to supplement our salary because things are costly, please our amiable governor should please us out as we are looking forward for the palliative.

    ReplyDelete

PÍN-IN KÁÀKIRI