Ijọba kede ọjọ karundinlọgbọn, ikẹrindinlọgbọn, oṣu kejila ọdun 2023 ati ọjọ kinni, oṣu kinni, ọdun 2024 gẹgẹ bi ọlude - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, December 22, 2023

Ijọba kede ọjọ karundinlọgbọn, ikẹrindinlọgbọn, oṣu kejila ọdun 2023 ati ọjọ kinni, oṣu kinni, ọdun 2024 gẹgẹ bi ọlude


Ijọba apapọ orileede Naijiria ti kede ọjọ karundinlọgbọn, ikẹrindinlọgbọn, oṣu kejila ọdun 2023 ati ọjọ kinni, oṣu kinni, ọdun 2024 gẹgẹ bi ọlude f'awọn araalu.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu kejila ni ọjọ ayẹyẹ ọdun Keresimesi ti awọn Kristẹẹni maa n ṣe lọdọọdun, eyi to jẹ ki ijọba apapọ kede ọjọ naa ati ọjọ keji rẹ gẹgẹ bi ọjọ isinmi fun gbogbo oṣiṣẹ patapata.

Minisita fọrọ eto abẹle Ọnarebu Olubunmi Tunji-Ojo lo sọ eyi di mimọ lọjọ Ẹti, Fraide, ọjọ kejilelogun, oṣu kejila niluu Abuja.
 
Ninu atẹjade ti adele akọwe agba ileeṣẹ to n ri sọrọ eto abẹle, Peter Egbodo buwọ lu, Tuni-Ojo sọ pe lati le fọkan balẹ ṣayẹyẹ ọjọ ibi Jesu ni ijọba ṣe kede isinmi.
 
Bakan naa lo gba awọn araalu lamọran lati ṣamulo igbesi aye Jesu nipa iwa, ẹkọ ati itọni lori ihuwasi, ifẹ, alaafia, iwa otitọ ti ọjọ ibi rẹ mu wa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI