Ẹ fi ọkan ifẹ ati akikanju sin ilẹ baba yin - Ijọba Kwara gba awọn agunbanirọ lamọran - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, December 1, 2023

Ẹ fi ọkan ifẹ ati akikanju sin ilẹ baba yin - Ijọba Kwara gba awọn agunbanirọ lamọran


Ijọba ipinlẹ Kwara ti gba gbogbo awọn agunbanirọ ti wọn lọ sin ilẹ baba wọn lamọran lati lo ọkan ifẹ ati akikanju lai ṣe magomago.

Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lo gba awọn agunbanirọ naa lamọran nibi eto imurasilẹ ọlọsẹ mẹta ti wọn bẹrẹ, iyẹn Orientation Exercise.

O ni ki wọn lo iwa ọmọluwabi ati oriṣiriṣi ẹkọ to ye kooro ti wọn yoo gba laarin ọsẹ mẹta lati fi ṣiṣẹ takuntakun gbe ilẹ baba wọn larugẹ.

AbdulRazaq ti amugbalẹgbẹ rẹ, Alaaji Saadu Salahu ṣoju fun nigba to n ba awọn agunbanirọ ti ipele kẹta (Batch C, Stream 2) ọhun sọrọ ni NYSC orientation Camp at yo wa ni Yikpata, ijọba ibilẹ Edu sọ pe iwa ọmọluwabi ṣe pataki pupọ.

O ni ki wọn lo gbogbo agbara ati okun to wa lara wọn, to fi mọ ọgbọn ati ẹbun lati mu idagbasoke ba Naijiria ni ẹka iṣẹ yoowu ti wọn yan laayo. 

Bẹẹ lo sọ pe ki awọn naa gunle afojusun awọn to da ajọ NYSC silẹ fun ilọsiwaju Naijiria.

Minisita f'ọrọ eto ipinlẹ ati idagbasoke awọn ọdọ (State Federal Ministry of Youth Development), Ọnarebu Ayọdele Ọlawale, nigba toun naa n sọrọ fọkan awọn agunbanirọ yii balẹ nipa iranwọ ijọba apapọ.

O ni titi digba ti wọn yoo fi pari eto agunbanirọ wọn ni ijọba apapọ yoo maa dide iranwọ si wọn lai fi ti ẹlẹyamẹya ṣe.

Kọmiṣanna f'ọrọ eto idagbasoke ọdọ n'ipinlẹ Kwara, Ọnarebu Usman Yunusa Lade fi idunnu rẹ han si gomina lori awọn iranwọ to ti ṣe fun awọn agunbanirọ.

Bakab naa ni Ọgbẹni Onifade Ọlaoluwa Joshua, to jẹ alakoso eto agunbanirọ n'ipinlẹ Kwara ninu ọrọ tiẹ naa dupẹ lọwọ gomina fun ifọwọsowọpọ rẹ ni gbogbo igba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI