Ẹ gbiyanju lati maa gbogun ti ayederu iroyin - Ajakaye parọwa fawọn akọroyin Musulumi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, December 21, 2023

Ẹ gbiyanju lati maa gbogun ti ayederu iroyin - Ajakaye parọwa fawọn akọroyin Musulumi


Awọn alẹnulọrọ ijọba Kwara ti parọwa si gbogbo awọn akọroyin Musulumi kaakiri agbaye lati maa gbogun ti ayederu iroyin to ba n jade sita lori ikanni iroyin ayelujara igbalode.

Rafiu Ajakaye to jẹ akọwe iroyin gomina lo parọwa yii l'Ọjọru, Wẹsidee ọsẹ yii nibi akanṣe eto ti wọn ṣagbekalẹ rẹ fawọn akọroyin Musulumi niluu Ilọrin.

Eto ọhun ti wọn pe akori rẹ ni  Muslim Media Executives and Gatekeepers/Journalists' Engagement, ni ajọ Hijrah Islamic Organization of Nigeria, ẹka tipinlẹ Kwara ṣagbatẹru ẹ.

Lara awọn alẹnulọrọ bii olugbaninimọran pataki si gomina, Alaaji Saadu Salau; oludamọran pataki lori ọrọ iroyin, Alaaji Bashir Adigun; Amugbalẹgbẹ agba pataki lori ọrọ ẹsun Musulumi, Alaaji Ibrahim Dan-meigoro; Alaga ajọ Hijrah Islamic Organisation, Ọjọgbọn Badmus Lanre Yusuf lo wa nibẹ.
 
Awọn miran to tun wa nibẹ ni alakoso Muslim Media Watch Group, Alaaji Ibrahim Abdullahi; alaga National League of Veteran Journalists (NALVEJ) ni Kwara, Alaaji Tunde Akanbi; alaga Muslim Media Practitioners in Nigeria, (MMPN), Ọmọwe Abdulrazaq Laaro; Kwara State FOMWAN Amirah, Alaaja Nimata Labaika; Alaaja Balikis Ọladimeji; ati awọn miran.

Nigba to n sọrọ lori akori to pe ni
Confronting the challenges of modern media by Muslims and Associations: role of Muslim media practitioners", Ajakaye ni ki awọn akọroyin rii daju pe wọn n ṣe iwadii kikun nipa iroyin ti wọn fẹẹ gbe jade, ki wọn si ma ṣe ojusaaju ko to di pe wọn gbe iroyin ọhun jade.

O ni ki wọn rii daju pe iroyin ti wọn fẹẹ gbe jade ko tako ilanaẹsin Islam, eyi to n gbe alaafia ati iṣọkan larugẹ lawọn agbegbe.
 
Bakan naa lo sọ pe ayederu iroyin wa n sare rinlẹ bii agba ina, to si ni ki awọn musulumi rii daju pe wọn ko ba ọbọ jawura nipa gbigbe iroyinẹlẹjẹ kaakiri, bi ko ṣe eyi ti yoo mu igbelarugẹ ba ẹsin wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI