COREN fọkan awọn araalu balẹ lori afara Tunde Idiagbon ati awọn akanṣe iṣẹ miran ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, December 21, 2023

COREN fọkan awọn araalu balẹ lori afara Tunde Idiagbon ati awọn akanṣe iṣẹ miran ni Kwara


Ẹgbẹ awọn onimọ-ẹrọ  lorileede Naijiria, Council for the Registration of Engineering in Nigeria (COREN) ti sọ pe ọkan awọn balẹ lori afara Tunde Idiagbon ati awọn akanṣe iṣẹ miran ti ijọba ti Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ṣe kaakiri ipinlẹ Kwara.

Ẹgbẹ naa lo sọ eyi di mimọ nbi abẹwo ti wọn ṣe lọ si afara Tunde Idiagbon ati awọn akanṣe iṣẹ miran kaakiri ipinlẹ Kwara laipẹ yii.

Ijọba Naijiria lo da ẹgbẹ naa silẹ pẹlu aṣẹ abala karundinlọgọta ti ọdun 1970 (Decree 55 of 1970) ti wọn si tun ṣe agbeyẹwo ẹ lọdun 2018 lati maa ṣagbeyẹwo iṣẹ ti awọn onimọ-ẹrọ n ṣe kakiri loriṣiriṣi ẹka.

Nigba to n b'awọn akọroyin sọrọ nibi abẹwo ti awọn adari ẹgbẹ naa ṣe si awọn ibi ti akanṣe iṣẹ to nii ṣe pẹlu Onimọ-ẹrọ ti waye ni Kwara kẹdun, wọn jẹ ko di mimọ pe ojulowo iṣẹ ni wọn ṣe.

Onimọ-ẹrọ Bashiru Lawal to jẹ alaga ẹka kan lẹgbẹ naa n'ipinlẹ Kwara sọ pe oun fi ọwọ sọya pe ojulowo irinṣẹ igbalode ni wọn lo s'awọn akanṣe iṣẹ to waye níbẹ.

Lara awọn akanṣe iṣẹ ti wọn lọ ṣabẹwo si ni afara Tunde Idiagbon, ile alaja mọkanla ti ileeṣẹ to n pawo wọle fun Kwara, Kwara State Internal Revenue Service (KWIRS), ṣagbatẹru kikọ rẹ ati awọn iṣẹ miran.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI