Emefiele gba itusilẹ kuro lẹwọn Kuje - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, December 23, 2023

Emefiele gba itusilẹ kuro lẹwọn Kuje


Gomina ana fun banki apapọ Naijiria, Central Bank of Nigeria, Godwin Emefiele ti gba itusilẹ kuro lọgba ẹwọn Kuje to wa lati bi oṣu meloo kan ṣeyin.
 
Ọjọ Ẹti, Fraide, ọsẹ yii ni Emefiele gba itusilẹ ni nnkan bi agogo meji ọsan, lẹyin to ri awọn oniduro gẹgẹ bi aṣẹ ile-ẹjọ.
 
Agbẹnusọ ọgba ẹwọn Kuje to wa niluu FCT, Adamu Duza nigba to n fi ọrọ naa lede, o ni awọn ohun ti ile-ẹjọ beere lọwọ Emefiele lati fi gba beeli rẹ lo ti ri ko silẹ.
 
Bẹ o ba gbagbe, Ile-ẹjọ giga tiluu Federal Capital Territory ti sọ pe ki Emefiele ba beeli ara rẹ pẹlu miliọnu lọna ọọdunrun naira lori ẹsun jibiti ti wọn fi kan an.
 
Yatọ si owo naa, yoo tun ni oniduro meji ti wọn gbọdọ ni iwe dukia to nii ṣe pẹlu ilẹ nigboro agbegbe Maitama, Abuja.
 
Bakan naa ni ile-ẹjọ tun sọ pe ki Emefiele fi iwe irinna oke-okun rẹ silẹ fun ile-ẹjọ, ti ko si gbọdọ kuro niluu Abuja.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI