Gomina Kwara bura fun kọmiṣanna tuntun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, December 22, 2023

Gomina Kwara bura fun kọmiṣanna tuntun


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lonii, ọjọ Ẹti, Fraide ti bura fun kọmiṣanna tuntun fọrọ itẹsiwaju awọn ọdọ, Ọnarebu Nafisat Musa Buge, to si gba a lamọran lati jẹ aṣoju rere fun ipinlẹ naa.

Gomina AbdulRazaq ni bi wọn ṣe yan Buge ko ṣẹyin awọn ipa to ti ko ninu itẹsiwaju ipinlẹ naa, ati pe o tun jẹ ọmọ ẹgbẹ rere.

Yatọ si Buge, gomina tun gba awọn ọmọ igbimọ tuntun lamọran lati farajin fun iṣẹ ti wọn gba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI