Ijọba Kwara gbe eto ayeyẹ opin ọdun kalẹ f'awọn araalu lara-ọtọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, December 20, 2023

Ijọba Kwara gbe eto ayeyẹ opin ọdun kalẹ f'awọn araalu lara-ọtọ


Gbogbo eto lo ti fẹẹ pari bayii fun ayẹyẹ opin ọdun ti ijọba Kwara fẹẹ gbe kalẹ f'awọn araalu lati waye niluu Ilọrin, ẹlẹẹkeji iru ẹ.

Eto ayẹyẹ naa ti wọn pe ni 'Christmas and End of Year 2023 in Kwara' ni yoo waye lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kejila, ọdun 2023 ni gbọngan ayẹyẹ Amusement Park to wa niluu Ilọrin.

Nigba to n fifi rẹ mulẹ, amugbalẹgbẹ agba pataki lori eto aṣa ati irin-ajo afẹ, Ọnarebu Muka Ray sọ pe lati le jẹ ki awọn araalu jẹ mudunmudun eto oṣelu awarawa ni ijọba fi n ṣagbatẹru eto ọhun.

O ni ipa rere ti ayẹyẹ tọdun to kọja mu wọ Kwara lo mu ki ẹlẹẹkeji yii fẹẹ waye.
 
Siwaju sii lo ni ọfẹ ni awọn eeyan yoo wọ gbọngan ayẹyẹ naa lati le jẹ ki wọn maa ni imọ ti wọn ko le gbagbe titilai.

1 comment:

PÍN-IN KÁÀKIRI