Ọwọ tẹ Matẹ, ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, December 20, 2023

Ọwọ tẹ Matẹ, ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun l'Abẹokuta


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti rọwọ to genedekunrin, ọmọ ọgbọn ọdun kan, Ademuyiwa Sọdiq Akanni ti ọpọ awọn ẹlẹgbẹ rẹ mọ si Matẹ lori ẹsun ṣiṣe ẹgbẹ okunkun.

Agbegbe Adigbẹ to wa niluu Abẹokuta, ipinlẹ naa lọwọ ti te Matẹ lọjọ Iṣẹgun, Tuside, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kejila, ọdun 2023.

Ikọ ọlọpaa to n gbogun ti ẹgbẹ okunkun lo rọwọ to Matẹ pẹli ibọn ilewọ ati ọta ibọn.
 
Agbẹnusọ ọlọpaa, Ọmọlọla Odutọla nigba to n sọrọ ṣalaye pe agogo mejila ọsan lọwọ tẹ Matẹ lẹyin olobo to tẹ wọn lọwọ.
 
O ni Matẹ wa pẹlu awọn ẹlẹgbẹ rẹ, ṣugbọn ti awọn yooku raaye na papa bora.

Bakan naa lo ni ọmọ ẹgbẹ okunkun Bukana ti wọn tun n pe ni Alora ni Matẹ jẹ,, to si lo ti n fun wọn ni awọn ohun to le mu ki iṣẹ iwadii wọn lọ daadaa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI