Ijọba Kwara pin ẹbun ọdun fawọn akanda ẹda - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, December 31, 2023

Ijọba Kwara pin ẹbun ọdun fawọn akanda ẹda


Lojuna lati le jẹ ki awọn naa jẹ igbadun mudunmudun eto iṣejọba awa-ara-wa, ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti pin ẹbun ọdun fawọn akanda ẹda lawujọ.

Awọn ẹbun naa lawọn ohun irinsẹ ti yoo jẹ ki irin wọn ya, ati awọn eyi ti yoo jẹ ki ilera tete jẹ ti wọn.

Kaakiri origun mẹrẹẹrin, ìyẹn ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa ni Kwara ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti pin awọn ẹbun naa.

Nigba to n sọrọ, gomina ni lara awọn eto toun maa n ṣe lọdọọdun lati fi mu ẹrin si awọn araalu, paapaa awọn alaabọ ara lẹnu ni pinpin awọn nnkan amuseya naa.

Lara awọn ẹbun naa ni wheel chairs, tricycles, guide canes, hearing aids, walking sticks ati crutches.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI