Iku ọdọ maa pọ lọdun 2024 nitori pe... - Gbajugbaja Wolii Ọlọrunmbẹ ju bọmbu asọtẹlẹ sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, January 1, 2024

Iku ọdọ maa pọ lọdun 2024 nitori pe... - Gbajugbaja Wolii Ọlọrunmbẹ ju bọmbu asọtẹlẹ sita


Gbajugbaja Wolii nni, Wolii Michael Ọlọrunmbẹ ti sọ pe ọdun 2024 ti a wa yii maa le gidi, ṣugbọn alaafia yoo jọba ki ọdun naa too pari.

Alaṣẹ ati oludasilẹ ijọ GOD LIVETH MINISTRY to wa niluu Ekoo lo sọrọ yii ninu awọn àsọtẹlẹ to gbe jade nipa ọdun 2024 ti a ṣẹṣẹ wọ yii.

Nigba to n sọrọ, o ni awọn asọtẹlẹ naa ko le ṣai ma wa si imuṣẹ, ṣugbọn to ni ki awọn eeyan kun fun adura gidigidi.

IRAN ỌDUN 2024

• Ọdun maa le gan an, ṣugbọn alaafia yoo wa ki ọdun too pari.

• Awọn Agbẹ ati gbogbo awọn to ba le tẹpa mọ iṣẹ wọn nikan ni yoo jere lọdun 2024.

• Darudapọ maa wa laarin awọn oloṣelu Naijiria, nitori ede aiyede maa bẹ silẹ laarin awọn alagbara lọdun yii.

• Awọn orileede kan maa gbe ogun ti ara wọn lọdun 2024.

• Awọn ọmọ Naijiria gbọdọ gbẹkẹle Ọlọrun lọdun 2024, ki wọn si tẹpa mọ iṣẹ wọn ki wọn ma baa jiya lọwọ ijọba orileede yii ati awọn ẹmi okunkun.

• Iku ọdọ to fẹẹ ipa lowo lọwọ maa pọ gidi lọdun 2024. Ki awọn ti alagbatọ kilọ fun awọn ọmọ wọn, paapaa awọn to n lu jibiti ori ayelujara.

• Ki onikaluku sunmọ Ọlọrun, ki iku ma baa kan wọn ati idile wọn. Ki awọn oṣere tiata ati awọn olorin ṣọra wọn.

• Ẹ jẹ ka gbadura fun Naijiria ki ọkọ oju irin, reluwee ma ba a ṣubu lulẹ lojiji, ko si ma baa gba ẹmi ọpọ awọn eeyan.

Ọlọrun ni ki n sọ fun gbogbo ọmọ orileede yii ti wọn ba fẹẹ fi irọrun, idẹra, alaafia, owo, igbega, ibukun, ibalẹ ọkan ati iranlọwọ ohun rere lo ọdun yii wa sinu ijọ GOD LIVETH MINISTRY fun adura pataki.

Ninu akanṣe eto ti Ọlọrun gbe kalẹ ni awọn to ba wa yoo ti fi abẹla (Candle) ayanmọ ogo titun beere ohun ti wọn ba n fẹ lọwọ Ọlọrun.

Ki ni iwọ n woju Ọlọrun fun lọdun 2024, ṣe ile lo fẹẹ kọ ni tabi mọto lo fẹẹ ra? Ileeṣẹ lo fẹẹ da silẹ ni tabi okoowo lo fẹẹ bẹrẹ? Ọkọ, aya irin-ajo lọ si oke-okun to maa mu ayọ wa ni iwọ n fẹ ni?

Wa ba Ọlọrun pade ninu ijọ wa to wa ni No 8, Ọmọbọgiẹ Street, Akinọde, Ojodu-Berger, Lagos.

Ọlọrun n ṣiṣẹ iyanu ninu ijọ wa, ti awọn eeyan si n jẹri si iṣẹ iyanu Ọlọrun lojoojumọ.

Fun ibeere ati alaye lẹkunrẹrẹ, e le pe awọn ẹrọ ibanisọrọ wọnyi; 0703603875 tabi 09135642057

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI