Ijọba Kwara pin ẹrọ amunawa 'tiransifọma' fun awọn araalu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, December 20, 2023

Ijọba Kwara pin ẹrọ amunawa 'tiransifọma' fun awọn araalu


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti pin awọn ẹrọ amunawa 'tiransifọma' fun awọn agbegbe marun-un ọtọọtọ ni ipinlẹ naa.

Eyi ni lati mu ilọsiwaju ba eto ọrọ aje awọn agbegbe wọnyi, gẹgẹ bi a ṣe gbọ ninu atẹjade ti akọwe iroyin ileeṣẹ ohun agbara, Rukayat Abdulhameed fi sita laipẹ yii.

Nigba to n sọrọ, Kọmiṣanna f'ọrọ ohun agbara, Onimọ-ẹrọ Kọla AbdulAzeez AbdulGaniy nibi eto ti wọn ti fa awọn tiransifọma naa le awọn araalu lọwọ, o ni yoo ṣe anfaani pupọ fun wọn.

Lara awọn agbegbe naa ni Balogun to wa ni Tanke Oke-Odo, ijọba ibilẹ Guusu Ilọrin; College of Arabic and Islamic Legal Studies (CAILS), ijọba ibilẹ Ilorin West; Gerewu to wa ni ijọba  ṣetan ibilẹ Ilorin West.

Awọn yooku ni agbegbe Reke ati Gbale Asun ti wọn wa ni ijọba ibilẹ Asa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI