Ileeṣẹ Adron Homes fi mọto bọginni ta akọroyin lọrẹ l'Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, December 20, 2023

Ileeṣẹ Adron Homes fi mọto bọginni ta akọroyin lọrẹ l'Ekoo


Alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Adron Homes lorileede Naijiria, Aarẹ Adetọla EmmanuelKing ti fa kọkọrọ mọto bọginni le ọkan lara awọn gbajugbaja akọroyin nipinlẹ Ekoo lọwọ.
 
Ọjọ Aiku, Sannde to kọja yii ni Aarẹ EmmanuelKing fa kọkọrọ mọto naa leakọroyin ọhun lọwọ lati mọ riri ipa to ko ninu idagbasoke ati ilọsiwaju ileeṣẹ naa laarin asiko perete ti wọn fi bẹrẹ ajọṣepọ.

Nibi eto ayẹyẹ opin ọdun ti ileeṣẹ Adron Homes fi mọ riri awọn akọroyin to n ba a ṣiṣẹ papọ ni Aarẹ Adetọla EmmaunelKing ti sọ pe oun ko le ṣai gb oriyin fun awọn akọroyin naa.

Nigba to n sọrọ, alaṣẹ naa sọ pe ileeṣẹ Adron Homes tun ti gun oke agba sii laigba toun ti tọwọbọwe adehun pẹlu akọroyin wọnyi, idi ree toun ṣe bẹrẹ irolagbara fun wọn.
 
O ni erongba ati ipinnu oun ni lati fun gbogbo awọn akọroyin to n ba a ṣiṣẹ ni mọto ti yoo mu ki iṣẹ wọn rọrun.
 
Bẹẹ lo lu wọn lọgọ ẹnu lati tẹpa mọ iṣẹ ti wọn yan laayo fun igbelarugẹ iṣẹ wọn.
 
Nibẹ lo tun ti kede yiyọ ida aadọta kuro lori owo ti wọn n ta awọn ilẹ wọn fun awọn akọroyin naa, to si ni anfaani wa fun wọn lati fi ọdun meji san owo naa.
 
Yatọ si ẹni to gba mọto bọginni yii, ileeṣẹ Adron Homes tun fi foonu olowo nla iPhone ati kọmputa alagbeka Macbook ta awọn akọroyin meji miran lọrẹ.
 
Wẹjẹwẹmu alailẹgbẹ la gbọ pe o ṣẹlẹ lọjọ naa, ti awọn akọroyin yii tun gba ẹbun ọdun lọ sile wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI