Iwa rere lo gbe Amofin Yahaya leke - AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, December 9, 2023

Iwa rere lo gbe Amofin Yahaya leke - AbdulRazaq


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti ba Amofin Ọlayiwọla Yahaya yọ lori bi Aarẹ Bọla Tinubu ṣe yan an gẹgẹ bi ọkan lara awọn alakoso ileeṣẹ National Council on Privatization (NCP).

Ẹkun Aarin Gbungbun Ariwa ipinlẹ Kwara ni Amofin Yahaya ti jade, ti a si gbọ pe o ti ko ipa takun-takun ninu idagbasoke ati ilọsiwaju ipinlẹ ọhun.

Yahaya to jẹ ọkan lara awọn ọrẹ Gomina AbdulRazaq ti jẹ akọwe igbimọ Kwara State Transition Implementation Committee (TIC), eyi ti wọn fi gbaradi fun ibura gomina lọdun 2019.

Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ni igi to tọ ni Amofin Yahaya si ipo ti wọn fun naa, nitori pe iwa rere ati ti ọmọluwabi lo fi n ṣe iranwọ fun idagbasoke ipinlẹ Kwara.

Bakan naa lo dupẹ lọwọ Aarẹ fun bo ṣe fun ipinlẹ Kwara ni ipo nla naa, to si loun nigbagbọ pe yoo ṣe daaadaa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI