Gbogbo eeyan kaakiri agbaye lo mọ pe eeyan nla kan wọlu Ilọrin, ipinlẹ Kwara lọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii, nigba ti igbakeji aarẹ orileede yii, Kashim Shettima wọ ilu naa.
Ẹsẹ ko gbero rara, nitori pe gbogbo araalu ni wọn lọ fi ifẹ ati ọyaya kii kaabọ, iyẹn lati papakọ ofurufu, titi de gbogbo ibi to lọ.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, aago mẹta ọsan geerege ni baluu igbakeji aarẹ balẹ si papakọ ofurufu ti Tunde Idiagbon, ti awọn agbaagba ipinlẹ naa si lọ lati pade rẹ.
Gomina ipinlẹ Kwara to tun jẹ alaga ẹgbẹ awọn gomina Naijiria, AbdulRahman AbdulRazaq lo lewaju awọn to lọ pade Shettima, to fi mọ igbakeji gomina, Kayọde Alabi.
Awọn oloye ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ naa, ati awọn bii olori ile igbimọ aṣofin Kwara, Ọnarebu Yakubu Salihu Danladi; Sẹnetọ Salihu Mustapha (Kwara Central); Sẹnetọ Sadiq Umar (North); alakoso ileeṣẹ KAM Holdings Nigeria, Alaaji Kamaru Yusuf ni wọn wa nibẹ.
Lara awọn to kọwọrin pẹlu igbakeji Aarẹ ni amugbalẹgbẹ pataki lori ọrọ oṣelu, Ọmọwe Hakeem Baba Ahmed; alẹnulọọ agba lẹgbẹ oṣelu APC, Ọmọwe Isia’q Modibbo Kawu; atawọn miran.
Bi wọn ṣe balẹ siluu Ilọrin ni gomina ti mu wọn lọ si fasiti Al-Hikmah to wa niluu Ilọrin, nibi ti ijọba ti kọ gbọgan awọn nọọsi to fi sọri igbakeji aarẹ.
Lẹyin ti Shettima ṣi gbọgan awọn nọọsi ọhun tan, lo lọ ṣe idanilẹkọọ nibi ayẹyẹ ikẹkọọjade ti fasiti naa ṣe f'awọn akẹkọọjade wọn, idanilẹkọọ to pe akori re ni 'Addressing Nigeria's Food Security Challenges Through Hi-Tech Approach: The Role of Nigerian Universities'.
Shettima, ninu ọrọ rẹ sọ pe bi Naijiria ṣe pa iṣẹ agbẹ ati ọgbin ti,to jẹ pe epo rọbii ni wọn gbajumọ lo fa awọn ipenija ti awọn eeyan koju lori ọrọ aisi eto aabo fun ounjẹ jijẹ.
O ni iwa ajẹbanu, aini abojuto gidi, ilana ti ko bojumu to, ayipada oju ọjọ, awọn agbesunmọmi, ajalu loriṣiriṣi lo fa aisi eto aabo lori ounjẹ ni Naijiria.
Nibẹ lo ti wa jẹ ko di mimọ pe ohun gbogbo to n ṣẹlẹ yii lo ye Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu, to si ti bẹrẹ igbesẹ lati mu ayipada rere ba aisi ounjẹ fawọn araalu.
Nigba to n kadi ọrọ rẹ nilẹ, igbakeji aarẹ gbe oṣuba rabandẹ fun gomina Kwara lori ọna to n gba lati mu idagbasoke ba eto iṣẹ agbẹ ati ọgbin lojuna lati gbogun ti aisi ounjẹ jijẹ to to fawọn araalu.
No comments:
Post a Comment