Orin 'ija d'opin, ogun si tan' ni oludije s'ipo gomina n'ipinlẹ Kwara lẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP ninu eto idibo ọdun 2023, Alaaji Shuaib Yaman Abdullahi kọ nigba ti Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ṣabẹwo sii nile rẹ to wa niluu Shonga aipẹ yii.
Nibẹ lo ti lọ gbe oṣuba rabandẹ fun gomina, to si ni ọna to n gba lati ṣakoso ipinlẹ ọhun wu ohun lori pupọ.
Gomina AbdulRazaq lo ṣabẹwo si Alaaji Shuaib Yaman Abdullahi nile rẹ to wa ni Shonga, ijọba ibilẹ Edu lọjọ Aiku, Sannde to kọja yii.
Yaman nigba to n sọrọ sọ pe iyalẹnu nla lo jẹ foun lati ri gomina nile ẹni ti wọn jọ du ipo kan naa ninu eto idibo to kọja lọ.
O ni ipa rere ni gomina fi le'lẹ yii, to si yẹ ki awọn oloṣelu maa mu lo.
Nigba to n sọrọ, o ni "Lakọkọ naa, mo gbe oriyin fun ẹ lati wa aaye wa ṣabẹwo si mi ati awọn yooku ti a jọ du ipo ninu eto idibo to kọja. Igbesẹ to dara leyi, to si yẹ ki a maa tẹle.
AbdulRazaq lo bẹrẹ abẹwo si gbogbo awọn ti wọn jọ du ipo gomina to gbe e wọle fun igbakeji.
Lara awọn to ti ṣabẹwo si ni awọn oludije lẹgbẹ oṣelu New Nigeria People’s Party (NNPP), Ọjọgbọn Shuaib Ọba Abdulraheem; ati olori ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party, SDP, Akọgun Iyiọla Oyedepo.
No comments:
Post a Comment