Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu ti sọ pe ki minisita fọrọ eto ohun to nii ṣe pẹlu ara ati eto adojutofo (Humanitarian Affairs and Poverty Alleviation) lorileede Naijiria, Omọwe Betta Edu lọ rọkun nile lori ẹsun iwa jibiti lai fi asiko ṣofo.
Agbẹnusọ Aarẹ Tinubu, Ajuri Ngelali lo gbe aṣẹ naa sita, lo si tun sọ pe aarẹ ti paṣẹ pe ki ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede yii, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC) ṣe iwadii finnifinni nipa ẹsun iwa jibiti ọhun.
Ngelali ni aarẹ paṣẹ pe ki ajọ EFCC tọpinpin bi owo ṣe n wọle-jade lati ileeṣẹ ti Edu di mu ati awọn ajọ to wa labẹ rẹ.
Bakan naa la gbọ pe Omọwe Betta Edu yoo gbe iṣẹ rẹ kalẹ fun akọwe agba ileeṣẹ naa, ati pe o tun gbọdọ jọwọ ara rẹ silẹ fun ajọ EFCC fun iwadii kikun.
Esun jibiti owo to le diẹ ni idaji biliọnu kan, N585,198,500.00 naira ni wọn fi kan Edu, ti wọon si lo ko owo ọhun ranṣẹ sinu apo ile ifowopamọ ẹnikan ṣoṣo.
Ninu lẹta kan ti wọn sọ pe Betta buwọ lu, wọn lo paṣẹ fun oluṣiro owo agba Naijiria, Oluwatoyin Madein lati san owo ọhun sinu apo ifowopamọsi Oniyelu Bridget gẹgẹ bi owo iranwọ fun awọn to ku diẹ kaato fun lawọno ipinlẹ mẹrin.
Ju gbogbo rẹ lọ, Madẹin nigba to n sọrọ ṣalaye pe lotitọ loun gba itọni lati ileeṣẹ ti Betta Edu dimu lati san awọn owo kan, ṣugbọn to loun ko ṣiṣẹ lee lori.
Edu, ẹni ọdun mẹtadinlogoji to kere julọ ninu awọn minisita Naijiria sọ pe lotitọ ni pe igbesẹ kan wa lati ba orukọ oun jẹ, nitori pe oun ko le lọwọ si iwa jibiti ati ajẹbanu.
No comments:
Post a Comment