Ọwọ wa ti tẹ awọn to wa nidi Gislover - Ọlọpaa Naijiria - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, January 8, 2024

Ọwọ wa ti tẹ awọn to wa nidi Gislover - Ọlọpaa Naijiria


Ileeṣẹ ọlọpaa orileede Naijiria ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ awọn mẹta kan ti wọn wa nidi biba awọn eeyan lorukọ jẹ lori ayelujara ti a mọ si Gistlover.
 
Agbẹnusọ agba fun ileeṣẹ ọlọpaa, Olumuyiwa Adejọbi lo sọ eyi di mimọ laipẹ yii, to si ni Ọnarebu kan to tun jẹ Ọmọwe, Arabinrin Ṣẹyẹ Ọladẹjọ lo ọwe ẹsun si awọn.

Lara ẹsun ti wọn fi kan awọn mẹtẹẹta ni igbimọ papọ, ọrọ alufanṣa ori ayelujara ati didunkoko mọ ẹmi eeyan.
 
Adebukọla Kọlapọ, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn; Nnedum Micheal Somtomchukwu, ẹni ọdun marundinlọgbọn ati Isaac Akpokighe toun jẹ ẹni ọgbọn ọdun lorukọ awọn mẹtẹẹta.
 
Ninu ọrọ rẹ, o ni ẹsun ti awọn fi kan wọn ni wọn ti n ṣe lati bi ọpọ ọdun sẹyin, to si maa n di ohun t'awọn eeyan  n sọ ni gbogbo igba.
 
Adejọbi ni pupọ oju opo Gistlover to wa lori ayelujara lo jẹ pe Adebukọla Kọlapọ ti ọpọ mọ si Ọmọ Ọba Gistlover lo ṣe wọn lati maa fi huwa ibaẹ lawujọ, ti wọn si ti n wa a tipẹ.

O tẹsiwaju pe awọn wọnyi ni wọn n gba owo oṣu, ti wọn si n jẹ awọn anfaani bi mọto ati owo.
 
Siwaju sii lo sọ pe awọn ti gba oju opo ayelujara mẹjọ ti Adebukọla ṣe nipa aṣẹ ọga wọn, ati apo owo ti wọn fi n gba owo lọwọ awọn eeyan.
  
Adejọbi ni awọn mẹtẹẹta ni wọn yoo foju ba ile-ẹjọ lẹyin ti iwadii ba tubọ pari lori wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI