Awa ko nii foju tẹmbẹlu Guinea-Bissau - Osimhen fọkan awọn ọmọ Naijiria balẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, January 19, 2024

Awa ko nii foju tẹmbẹlu Guinea-Bissau - Osimhen fọkan awọn ọmọ Naijiria balẹ


Ilu-mọ-ọn-ka agbabọọlu ikọ Super Eagles ti orileede Naijiria, Victor Osimhen ti sọ pe awọn ko nii fi oju tẹmbẹlu wo akẹgbẹ wọn lati orileede
Guinea-Bissau ninu ifẹsẹwọnsẹ ti yoo waye lọjọ Aiku, Sande to n bọ yii.
 
Osimhen lo sọrọ naa laipẹ yii lẹyin ti doju akẹgbẹ wọn, Cote d’Ivoire bolẹ lalẹ ana, Tọside, ninu idijẹ ifẹ ẹyẹ ilẹ Afrika, AFCON ti ọdun 2023 to n lọ lọwọ.
 
Awọn ọmọ ẹyin akọnimọ-ọngba Jose Peseiro naa yoo koju akẹgbẹ wọn, Djurtus ni papa iṣere Felix Houphouet Boigny to wa niluu Abidjan lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to m bọ.
 
Ifẹsẹwọnsẹ meji ti ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Guinea-Bissau ti gba pẹlu Cote d’Ivoireati Equatorial Guinea ni wọn padanu, leyi ti ko fun wọn ni oore ọfẹ lati kọja ipele ti wọn wa.
 
Osimhen, nigba to n sọrọ ti wa ṣalaye pe awọn yoo fi gbogbo ọkan gba ifẹsẹwọnsẹ ọhun pẹlu erongba lati bori wọn.
 
O tẹsiwaju pe awọn ko ṣẹṣẹ maa pade ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Guinea-Bissau, o lawọn pade lẹẹmeji ọtọọtọ lakoko igbaradi ti wọn si jọ bori nile wọn, ṣugbọn to lawọn ko nii foju yẹpẹrẹ wo wọn lakoko yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI