Oloye ati awọn mẹta ti wọn jigbe ni Kwara ti gba itusilẹ - Ọlọpaa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, January 19, 2024

Oloye ati awọn mẹta ti wọn jigbe ni Kwara ti gba itusilẹ - Ọlọpaa


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti sọ ọ di mimọ pe awọn mẹrin ti wọn jigbe labule Afin to wa ni ẹkun Ilere, ijọba ibilẹ Ifẹlodun lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tuside ti gba itusilẹ.
 
Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, DSP Ejirẹ Adetoun Adeyẹmi lo sọ eyi di mimọ pe Simon Ibiwoye to jẹ Olukọtun ti Afin ati awọn ọmọde mẹta miran ti gba itusilẹ.
 
Adeyẹmi sọ pe niṣe lawọn ajinigbe ọhun fi wọn silẹ lati maa lọ funra wọn, ko to di pe awọn ọlọdẹ ibilẹ pade wọn lọna, ti wọn si ko wọn sile lọ fawọn mọlẹbi wọn.
 
Bakan naa lo ni ọwọ ti tẹ awọn mẹta ti wọn n ṣiṣẹ agbodegba fawọn ajinigbe yii, ti wọn si ti wa nibi ti wọn ti n fọrọ wa wọn lẹnu wo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI