Ẹgbẹ oṣiṣẹ yari ni Kwara, wọn lawọn fun AbdulRazaq ni gbedeke ọjọ mẹrinla lati dahun ibeere wọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, January 10, 2024

Ẹgbẹ oṣiṣẹ yari ni Kwara, wọn lawọn fun AbdulRazaq ni gbedeke ọjọ mẹrinla lati dahun ibeere wọn


Apapọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorileede Naijiria, ẹka ti ipinlẹ Kwara ti sọ pe awọn fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ni gbedeke ọjọ mẹrinla lati gbọ gbogbo ẹbẹ wọn, bi bẹẹ kọ, awọn yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi.
 
Ninu atẹjade ti alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ Nigeria Labour Congress, NLC, Murtala Saheed Ọlayinka; Tunde Joseph to jẹ alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ Trade Union Congress, TUC, ati and Saliu Suleiman toun jẹ alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ Joint Negotiation Council, JNC, nipinlẹ naa, wọn ni awọn fẹ ki gomina buwọ lu ẹgbẹrun marundinlogoji naira gẹgẹ bi owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ.
 
Wọn ni latigba ti owo epo rọbii ti lọ soke, ni ijọba apapọ orileede Naijiria ti paṣẹ pe ki awọn ipinlẹ maa san ẹgbẹrun marundinlogoji gẹgẹ bi owo oṣu to kere julọ, ṣugbọn ti ijọba Kwara kọ lati san.
 
Nibi ipade akọroyin ti awọn ẹgbẹ naa ṣe niluu Ilọrin, wọn tun fẹsun kan gomina pe ko buwọ lu ida ogoji gẹgẹ bi owo ajẹmọnu, eyi ti ijọba apapọ paṣẹ rẹ.
 
Lara awọn ẹbẹ miran ni sisan owo oṣu awọn oṣiṣẹ fẹyinti ti ijọba apapọ fọwọ si lati ọdun 2019, ati bi gomina ṣe mọ-ọn-mọ kọ lati san owo oṣu ajẹẹlẹ awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI