Ileeṣẹ Multichoice ti wọn ni DStv ati GOtv ti kede sita pe awọn ti ṣetan lati yọ tẹlifiṣan Emmanuel TV to jẹ ti ṣọọṣi Synagogue Church of All Nations, SCOAN, eyi ti Oloogbe Temitọpẹ Joshua ti ọpọ mọ si TB Joshua da silẹ.
Eyi la gbọ pe o waye lẹyin iroyin iwadii kikun ti ileeṣẹ iroyin British Broadcasting Corporation, BBC gbe jade laipẹ yii.
Ninu iwadii naa ni wọn ti tu gbogbo awọn aṣiri nipa awọn iwa buruku ti wọn sọ pe TB Joshua fi ṣọọṣi rẹ hu nigba to wa laye.
Multichoice ninu atẹjade ti wọn gbe sita laipẹ yii ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe awọn yoo yọ tẹlifiṣan Emmanuel TV kuro lori awọn ikanni wọn lati ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kinni, ọdun 2024.
“Ẹyin oluwaoran wa, a fẹ ki ẹ mọ pe tẹlifiṣan Emmanuel ko nii si lori ikanni wa mọ lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kinni, ọdun 2024. Ẹ ṣeun bi ẹ ti n wo wa.”
Yatọ si ti ileeṣẹ MultiChoice, a gbọ pe Emmanuel TV ko tun ni si lori awọn ikanni bii StarSat ati awọn miran mọ.
No comments:
Post a Comment