Habila, akẹkọọ fasiti to n lo ibọn ha sọwọ ọlọpaa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 18, 2024

Habila, akẹkọọ fasiti to n lo ibọn ha sọwọ ọlọpaa


Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Bauchi ti tẹ gendekunrin, akẹkọọ fasiti Abubakar Tafawa Balewa (ATBU) to wa nipinlẹ naa, Mike James Habila lori ẹsun wi pe o n lo ibọn ilewọ lai gba iwe aṣẹ.
 
Ipele kẹrin (400-level) ni wọn sọ pe Habila wa ni fasiti ọhun ki ọwọ palaba rẹ too segi ni ibugbe awọn akẹkọọ to wa ni abule kan ti wọn pe ni Gubi.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ninu oṣu kejila, ọdun to kọja ni ọwọ tẹ ọmọ ọdun mẹtalalelogun to jẹ akẹkọọ fasiti naa, ẹni ti wọn lo wa ni ipele kẹta

Iwadii lo pada fidi rẹ mulẹ pe Habila naa wa lara awọn akẹkọọ to n lọ ibọn lati maa fi dunkoko mọ awọn eeyan.
 
Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, SP Ahmed Wakil, ninu atẹjade to gbe sita f'awọn akọroyin l'Ọjọru, Wẹside, ọsẹ yii lo ti jẹ ko di mimọ pe ibọn ilewọ meji ọtọọtọ lawọn gba lọwọ Habila, pẹlu ọta ibọn.

O ni ọjọ kẹtala, oṣu yii ni awọn ọlọpaa pẹlu iranlọwọ awọn fijilante rọwọ to Habila, lẹyin olobo to tẹ wọn lọwọ.

Wakil ni Habila sọ pe Samson Irimiya ti inagijẹ rẹ n jẹ Zaddeos, ẹni tọwọ tẹ lọjọ kẹrinlelogun, oṣu karun, ọdun 2021 lo ni awọn ibọn naa, kii ṣe ohun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI